ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
6 : 39

خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۚ يَخۡلُقُكُمۡ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ خَلۡقٗا مِّنۢ بَعۡدِ خَلۡقٖ فِي ظُلُمَٰتٖ ثَلَٰثٖۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ

Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fún yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ- tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta.[1] Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo? info

1. Àpò (tán-ánná), ilé ọmọ àti ikùn ni àwọn okùnkùn mẹ́ta náà.

التفاسير:

external-link copy
7 : 39

إِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنكُمۡۖ وَلَا يَرۡضَىٰ لِعِبَادِهِ ٱلۡكُفۡرَۖ وَإِن تَشۡكُرُواْ يَرۡضَهُ لَكُمۡۗ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرۡجِعُكُمۡ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Tí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fún yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 39

۞ وَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَا رَبَّهُۥ مُنِيبًا إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُۥ نِعۡمَةٗ مِّنۡهُ نَسِيَ مَا كَانَ يَدۡعُوٓاْ إِلَيۡهِ مِن قَبۡلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَندَادٗا لِّيُضِلَّ عَن سَبِيلِهِۦۚ قُلۡ تَمَتَّعۡ بِكُفۡرِكَ قَلِيلًا إِنَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلنَّارِ

Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ lẹ́ni tí ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun tó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ (’Islām). Sọ pé: “Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná.” info
التفاسير:

external-link copy
9 : 39

أَمَّنۡ هُوَ قَٰنِتٌ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ سَاجِدٗا وَقَآئِمٗا يَحۡذَرُ ٱلۡأٓخِرَةَ وَيَرۡجُواْ رَحۡمَةَ رَبِّهِۦۗ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلَّذِينَ يَعۡلَمُونَ وَٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَۗ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ

Ǹjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (tó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, tó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, tó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: “Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l’ó ń lo ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 39

قُلۡ يَٰعِبَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ لِلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۗ وَأَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٌۗ إِنَّمَا يُوَفَّى ٱلصَّٰبِرُونَ أَجۡرَهُم بِغَيۡرِ حِسَابٖ

Sọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí.[1] Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò.² Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ láì níí ní ìṣírò.” info

1. Ó tún túmọ̀ sí “Àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí, ẹ̀san rere wà fún wọn.” 2. Ìyẹn ni pé, bí ṣíṣe ẹ̀sìn Allāhu ’Islām, kò bá rọrùn ní àdúgbò tàbí ìlú kan, ẹ kúrò níbẹ̀, kí ẹ lọ máa ṣe ẹ̀sìn yín ní àyè mìíràn.

التفاسير: