1. Èyí já sí pé Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - ń rin ìrìn oṣù méjì ní ojúmọ́ bí ó bá fẹ́ rìn jáde pẹ̀lú atẹ́gùn.
1. Ní àsìkò Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -, gbígbẹ́ ère fún fífi ṣe ọ̀ṣọ́ sínú ilé kì í ṣe èèwọ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀, yálà ó jẹ́ ère tàbí àwòrán n̄ǹkan abẹ̀mí. 2. Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn àwo tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe sínú ilé ìwẹ̀ tí ènìyàn máa ń wẹ̀ nínú rẹ̀ “bath tub”. 3. Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn apẹ irin ìdáná ńlá ńlá.