1. Àwọn ahlul-kitāb wọ̀nyẹn ni àwọn yẹhudi tí wọ́n ń jẹ́ banū Ƙuraeṭḥọh, tí wọ́n ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àwọn wọ̀nyí mọ odi ńlá ńlá yípo àwọn ilé wọn fún ààbò ogun. Àwọn wọ̀nyí l’ó ṣe agbódegbà fún àwọn ọmọ ogun oníjọ. Lẹ́yìn tí Allāhu Alágbára sì dójú ti àwọn ọmọ ogun oníjọ tán, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fàbọ̀ sórí wọn.