1. Níkété tí Allāhu - tó ga jùlọ - sọ āyah yìí kalẹ̀ ni àwọn Sọhābah -kí Allāhu yọ́nú sí wọn - bèèrè ohun tí àwọn náà yóò fi máa tọrọ ìkẹ́ fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì kọ́ wọn ní as-sọlātu al-’Ibrọ̄hīmiyyah. Ẹ̀gbàwá kan nìyí: اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ اللَّهُمَّ بَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ كَمَا بَارَكْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ. Allahummọ sọlli ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin kamọ̄ sọllaeta ‘alā āli ’Ibrọ̄hīmọ ’innaka Hamīdun Mọjīd. Allahummọ bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin kamọ̄ bārọkta ‘alā āli ’Ibrọ̄hīmọ ’innaka Hamīdun Mọjīd (Allāhu kẹ́ Ànábì Muhammad àti àwọn ará ilé Ànábì Muhammad gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe kẹ́ ará ilé Ànábì ’Ibrọ̄hīm, dájúdájú Ìwọ ni Ẹlẹ́yìn, Ológo. Allāhu bùkún Ànábì Muhammad àti àwọn ará ilé Ànábì Muhammad gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe bùkún ará ilé Ànábì ’Ibrọ̄hīm, dájúdájú Ìwọ ni Ẹlẹ́yìn, Ológo.) Bukọ̄riy àti Muslim Gbólóhùn wọ̀nyí tún tọ sunnah; “sọlla-llāhu ‘aleehi wa sallam” tàbí “‘aleehi sọlātun wa salām.” ìyẹn nígbàkígbà tí wọ́n bá dárúkọ rẹ̀. Èyí sì jẹ́ ohun àjogúnbá láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn Sọhābah rẹ̀ - kí Allāhu yọ́nú sí gbogbo wọn -.
1. Ọ̀nà tí ẹ̀dá ń gbà fi ìnira kan Allāhu - Ọba tí ìnira kì í kàn - nìwọ̀nyí; àìgbàgbọ́ nínú Allāhu, ìṣẹbọ sí Allāhu, ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn Rẹ̀, ṣíṣe àfitì ìyàwó àti ọmọ bíbí tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, pípa irọ́ mọ́ Ọn àti bíbú ìgbà, yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kíyè sí i, fífi ìnira kan Allāhu, Ọbá tí kò sí ìnira fún, kò ní ìtúmọ̀ kan tayọ pé ẹ̀dá ń wá ìnira ọ̀run fún ẹ̀mí ara rẹ̀.
1. Fún àgbọ́yé āyah yìí, ẹ lọ ka sūrah an-Nūr; 24:31 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.
1. Ìyẹn àwọn olófòófó tí wọ́n ń sọ ohun tí ojú wọn kò tó káàkiri láti dá rògbòdìyàn, ìpáyà àti wàhálà sílẹ̀ láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo.