1. Kò sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan t’ó dá iṣẹ́ ìyanu ṣe láti ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ bí kò ṣe èyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá yọ̀ǹda fún un láti ṣe nítorí pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - l’Ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan tí Allāhu kò fún ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe ní ìbámu sí ìgbà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni èyíkéyìí iṣẹ́ ìyanu tí ó bá tọwọ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan wáyé kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ náà di olúwa àti olùgbàlà. Allāhu nìkan ṣoṣo ní Olúwa àti Olùgbàlà ayé àti ọ̀run.