ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
14 : 20

إِنَّنِيٓ أَنَا ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدۡنِي وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِذِكۡرِيٓ

Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.[1] info

1. Láti ọ̀dọ̀ ’Anas bun Mọ̄lik, ó sọ pé. Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Tí ọ̀kan nínú yín bá sùn tayọ (àsìkò) ìrun tàbí ó gbàgbé (ìrun) rẹ̀, kí ó kí i nígbà tí ó bá rántí rẹ̀, nítorí pé Allāhu sọ pé: “Kírun fún ìrántí Mi.”

التفاسير: