ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
58 : 2

وَإِذۡ قُلۡنَا ٱدۡخُلُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ فَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ رَغَدٗا وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا وَقُولُواْ حِطَّةٞ نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطَٰيَٰكُمۡۚ وَسَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí.[1] Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà (ìlú) náà wọlé ní ìtẹríba.² Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere. info

1. Ìlú náà ni Baetul-Mọƙdis. 2. “Sujūd” tí ó wà nínú “Sujjadān” kò níí ṣe é túmọ̀ sí ìforíkanlẹ̀ nínú āyah yìí bí kò ṣe ìtẹríba. Wulẹ̀ tẹ́lẹ̀, ohun tí “sujūd” kó sínú ni ìtẹrùn wálẹ̀ “inhinā’”, ìdáwọ́tẹ-orúnkún “rukū‘” àti ìforíkanlẹ̀ “sujūd”.

التفاسير: