ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
50 : 18

وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ كَانَ مِنَ ٱلۡجِنِّ فَفَسَقَ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِۦٓۗ أَفَتَتَّخِذُونَهُۥ وَذُرِّيَّتَهُۥٓ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِي وَهُمۡ لَكُمۡ عَدُوُّۢۚ بِئۡسَ لِلظَّٰلِمِينَ بَدَلٗا

(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùjànnú. Ó sì yapa sí àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ máa mú òun àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ní aláfẹ̀yìntì lẹ́yìn Mi ni, ọ̀tá yín sì ni wọ́n. Pàṣípààrọ̀ tó burú ni fún àwọn alábòsí.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, aburú ni fún ẹni tí ó mú aṣ-ṣaetọ̄n ní aláfẹ̀yìntì rẹ̀ dípò Allāhu.

التفاسير: