1. Híhù tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - mú igi zaƙūm hù jáde láti inú Iná jẹ́ ohun tí ó tako òye àwọn aláìgbàgbọ́. Wọ́n takò ó. Àtakò wọn sì di àdánwò fún wọn.
1. Ìyẹn ni pé, aṣ-ṣaetọ̄n yóò bá wọn lọ́wọ́ sí fífi harām wá owó àti dúkìá. Bákan náà, aṣ-ṣaetọ̄n yóò bá wọn lọ́wọ́ sí bíbí ọmọ ní ìpasẹ̀ ìbàjẹ́ àti àgbèrè ṣíṣe. 2. Ohùn aṣ-ṣaetọ̄n ni orin àlùjó oníran-ànran, eré ṣíṣe àti ayò títa. Àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin àti àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ tí aṣ-ṣaetọ̄n ń lò fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí ni gbogbo olùpèpè sínú ìyapa àṣẹ Allāhu àti àṣẹ àwọn Ànábì Rẹ̀ (‘aleehim sọlātun wa salām).