ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
56 : 16

وَيَجۡعَلُونَ لِمَا لَا يَعۡلَمُونَ نَصِيبٗا مِّمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡۗ تَٱللَّهِ لَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَفۡتَرُونَ

Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò nímọ̀ nípa rẹ̀.[1] Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́. info

1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ń pe àwọn n̄ǹkan kan ní n̄ǹkan òrìṣà bí àpẹ̀ẹrẹ, wọ́n ń pe àwọn ẹran kan ní ẹran òrìṣà, wọ́n sì ń fi àwọn kan rúbọ fún àwọn òrìṣà wọn.

التفاسير: