ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
21 : 14

وَبَرَزُواْ لِلَّهِ جَمِيعٗا فَقَالَ ٱلضُّعَفَٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعٗا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا مِنۡ عَذَابِ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۚ قَالُواْ لَوۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُ لَهَدَيۡنَٰكُمۡۖ سَوَآءٌ عَلَيۡنَآ أَجَزِعۡنَآ أَمۡ صَبَرۡنَا مَا لَنَا مِن مَّحِيصٖ

Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn tó ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?” Wọn yóò wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa.” info
التفاسير: