Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

Ash-Sham's

external-link copy
1 : 91

وَٱلشَّمۡسِ وَضُحَىٰهَا

Allāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 91

وَٱلۡقَمَرِ إِذَا تَلَىٰهَا

Ó tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 91

وَٱلنَّهَارِ إِذَا جَلَّىٰهَا

Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 91

وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰهَا

Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 91

وَٱلسَّمَآءِ وَمَا بَنَىٰهَا

Ó tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n[1] búra? info

1. Allāhu - Ẹlẹ́dàá - ni Ẹni tí Ó mọ àwọn sánmọ̀. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.

التفاسير:

external-link copy
6 : 91

وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا طَحَىٰهَا

Ó tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 91

وَنَفۡسٖ وَمَا سَوَّىٰهَا

Ó tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 91

فَأَلۡهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقۡوَىٰهَا

Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 91

قَدۡ أَفۡلَحَ مَن زَكَّىٰهَا

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:4.

التفاسير:

external-link copy
10 : 91

وَقَدۡ خَابَ مَن دَسَّىٰهَا

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 91

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ بِطَغۡوَىٰهَآ

Ìjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 91

إِذِ ٱنۢبَعَثَ أَشۡقَىٰهَا

(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa). info
التفاسير:

external-link copy
13 : 91

فَقَالَ لَهُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ نَاقَةَ ٱللَّهِ وَسُقۡيَٰهَا

Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).” info
التفاسير:

external-link copy
14 : 91

فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمۡدَمَ عَلَيۡهِمۡ رَبُّهُم بِذَنۢبِهِمۡ فَسَوَّىٰهَا

Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 91

وَلَا يَخَافُ عُقۡبَٰهَا

(Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn. info
التفاسير: