Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

Nomor Halaman:close

external-link copy
68 : 7

أُبَلِّغُكُمۡ رِسَٰلَٰتِ رَبِّي وَأَنَا۠ لَكُمۡ نَاصِحٌ أَمِينٌ

Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fún yín. Èmi sì ni onímọ̀ràn rere, olùfọkàntán fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
69 : 7

أَوَعَجِبۡتُمۡ أَن جَآءَكُمۡ ذِكۡرٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَلَىٰ رَجُلٖ مِّنكُمۡ لِيُنذِرَكُمۡۚ وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ جَعَلَكُمۡ خُلَفَآءَ مِنۢ بَعۡدِ قَوۡمِ نُوحٖ وَزَادَكُمۡ فِي ٱلۡخَلۡقِ بَصۜۡطَةٗۖ فَٱذۡكُرُوٓاْ ءَالَآءَ ٱللَّهِ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ

Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín, nítorí kí ó lè kìlọ̀ fún yín? Ẹ rántí nígbà tí (Allāhu) fi yín ṣe àrólé lẹ́yìn ìjọ (Ànábì) Nūh. Ó tún ṣe àlékún agbára fún yín nínú ìṣẹ̀dá (yín). Nítorí náà, ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, nítorí kí ẹ lè jèrè.” info
التفاسير:

external-link copy
70 : 7

قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِنَعۡبُدَ ٱللَّهَ وَحۡدَهُۥ وَنَذَرَ مَا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí á lè jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo àti nítorí kí á lè pa ohun tí àwọn bàbá ńlá wa ń jọ́sìn fún tì? Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn olódodo.” info
التفاسير:

external-link copy
71 : 7

قَالَ قَدۡ وَقَعَ عَلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُمۡ رِجۡسٞ وَغَضَبٌۖ أَتُجَٰدِلُونَنِي فِيٓ أَسۡمَآءٖ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّا نَزَّلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٖۚ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ

Ó sọ pé: “Ìyà àti ìbínú kúkú ti sọ̀kalẹ̀ sórí yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣé ẹ óò máa jà mí níyàn nípa àwọn orúkọ (òrìṣà) kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fún lórúkọ - Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ lórí rẹ̀? - Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.” info
التفاسير:

external-link copy
72 : 7

فَأَنجَيۡنَٰهُ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَقَطَعۡنَا دَابِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَاۖ وَمَا كَانُواْ مُؤۡمِنِينَ

Nítorí náà, pẹ̀lú àánú láti ọ̀dọ̀ Wa, A gba òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ là. A sì pa àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ run pátápátá; wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
73 : 7

وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ قَدۡ جَآءَتۡكُم بَيِّنَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡۖ هَٰذِهِۦ نَاقَةُ ٱللَّهِ لَكُمۡ ءَايَةٗۖ فَذَرُوهَا تَأۡكُلۡ فِيٓ أَرۡضِ ٱللَّهِۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ìran Thamūd, arákùnrin wọn Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀rí kan (iṣẹ́ ìyanu kan) kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín; èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. (Ó jẹ́) àmì kan fún yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ aburú kàn án nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baà jẹ yín. info
التفاسير: