1. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, Allāhu fi ìràwọ̀ nígbà tí ó bá wálẹ̀ (wọ̀ọ̀kùn ní ìdájí) búra. Àmọ́ ìtúmọ̀ àkọ́kọ́ ló súnmọ́ jùlọ ní ìbámu sí sàkánì rẹ̀ pẹ̀lú àwọn āyah tí ó tẹ̀lé e. Wòóore! Wọ́n ń pe gbólóhùn ẹyọ kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān ní “an-najm”. Wọ́n sì ń pe ìràwọ̀ ní “an-najm”. Kódà “ìtàkùn” náà ń jẹ́ “an-najm” nínú èdè Lárúbáwá.(Tafsīr ’Adwā’ul-bayān)
1. Igun kan nínú àwọn àáfà sọ pé, mọlāika Jibrīl ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rí. Igun kejì sì sọ pé, Allāhu - tó ga jùlọ - ni ó rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu, kì í ṣe ojú.
1. Ìyẹn ni pé, ẹ má ṣe yin ara yín.