Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

Nomor Halaman:close

external-link copy
11 : 42

فَاطِرُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ أَزۡوَٰجٗا يَذۡرَؤُكُمۡ فِيهِۚ لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ

(Òun ni) Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ṣẹ̀dá àwọn obìnrin fún yín láti ara yín. Ó tún ṣẹ̀dá àwọn abo ẹran-ọ̀sìn láti ara àwọn akọ ẹran-ọ̀sìn. Ó ń mu yín pọ̀ sí i (nípa ìṣẹ̀dá yín ní akọ-abo). Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 42

لَهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ

TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ilé ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 42

۞ شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحٗا وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَمَا وَصَّيۡنَا بِهِۦٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓۖ أَنۡ أَقِيمُواْ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُواْ فِيهِۚ كَبُرَ عَلَى ٱلۡمُشۡرِكِينَ مَا تَدۡعُوهُمۡ إِلَيۡهِۚ ٱللَّهُ يَجۡتَبِيٓ إِلَيۡهِ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَن يُنِيبُ

(Allāhu) ṣe ní òfin fún yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé, kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà). info
التفاسير:

external-link copy
14 : 42

وَمَا تَفَرَّقُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى لَّقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُورِثُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ

(Àwọn ọ̀ṣẹbọ) kò sì pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tí ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (pé Òun yóò lọ́ wọn lára) títí di gbèdéke àkókò kan ni, Wọn ìbá ti dájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú àwọn tí A jogún Tírà fún lẹ́yìn wọn sì tún wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa ’Islām. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 42

فَلِذَٰلِكَ فَٱدۡعُۖ وَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡۖ وَقُلۡ ءَامَنتُ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِن كِتَٰبٖۖ وَأُمِرۡتُ لِأَعۡدِلَ بَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ رَبُّنَا وَرَبُّكُمۡۖ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡۖ لَا حُجَّةَ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَاۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ

Nítorí ìyẹn, pèpè (sínú ’Islām), kí o sì dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Wọ́n ṣe pa ọ́ lásẹ. Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Kí o sì sọ pé: “Mo gbàgbọ́ nínú èyíkéyìí Tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Wọ́n sì pa mí láṣẹ pé kí n̄g ṣe déédé láààrin yín. Allāhu ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kò sí ìjà láààrin àwa àti ẹ̀yin.[1] Allāhu l’Ó sì máa kó wa jọ papọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.” info

1. Ìyẹn ṣíwájú àwọn āyah tó ń páṣẹ ogun ẹ̀sìn jíjà.

التفاسير: