Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

Nomor Halaman:close

external-link copy
116 : 3

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡـٔٗاۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ

Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan (níbi ìyà) lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
117 : 3

مَثَلُ مَا يُنفِقُونَ فِي هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَثَلِ رِيحٖ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتۡ حَرۡثَ قَوۡمٖ ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَأَهۡلَكَتۡهُۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِنۡ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ

Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn tó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí. info
التفاسير:

external-link copy
118 : 3

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ بِطَانَةٗ مِّن دُونِكُمۡ لَا يَأۡلُونَكُمۡ خَبَالٗا وَدُّواْ مَا عَنِتُّمۡ قَدۡ بَدَتِ ٱلۡبَغۡضَآءُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَمَا تُخۡفِي صُدُورُهُمۡ أَكۡبَرُۚ قَدۡ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡقِلُونَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ finúhannú kan yàtọ̀ sí ara yín. Wọn kò níí géwọ́ aburú kúrú fún yín. Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó máa kó ìnira ba yín. Ìkórira kúkú ti fojú hàn láti ẹnu wọn. Ohun tí ó sì pamọ́ sínú ọkàn wọn tóbi jùlọ. A ti ṣàlàyé àwọn āyah fún yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onílàákàyè.[1] info

1. Ẹ wo āyah 28.

التفاسير:

external-link copy
119 : 3

هَٰٓأَنتُمۡ أُوْلَآءِ تُحِبُّونَهُمۡ وَلَا يُحِبُّونَكُمۡ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱلۡكِتَٰبِ كُلِّهِۦ وَإِذَا لَقُوكُمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَوۡاْ عَضُّواْ عَلَيۡكُمُ ٱلۡأَنَامِلَ مِنَ ٱلۡغَيۡظِۚ قُلۡ مُوتُواْ بِغَيۡظِكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn kò sì nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú gbogbo àwọn tírà pátápátá. Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé yín, wọ́n á wí pé: “Àwa gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku àwọn nìkan, wọn yóò máa deyín mọ́ ìka lórí yín ní ti ìbínú. Sọ pé: “Ẹ kú pẹ̀lú ìbínú yín.” Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
120 : 3

إِن تَمۡسَسۡكُمۡ حَسَنَةٞ تَسُؤۡهُمۡ وَإِن تُصِبۡكُمۡ سَيِّئَةٞ يَفۡرَحُواْ بِهَاۖ وَإِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ لَا يَضُرُّكُمۡ كَيۡدُهُمۡ شَيۡـًٔاۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعۡمَلُونَ مُحِيطٞ

Tí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan bá yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.́ info
التفاسير:

external-link copy
121 : 3

وَإِذۡ غَدَوۡتَ مِنۡ أَهۡلِكَ تُبَوِّئُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ مَقَٰعِدَ لِلۡقِتَالِۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

(Rántí) nígbà tí o jí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ara ilé rẹ ní ìdájí kùtùkùtù, tí ò ń fi àwọn onígbàgbọ́ òdodo sí àyè ibùjagun, Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀. info
التفاسير: