Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

external-link copy
8 : 21

وَمَا جَعَلۡنَٰهُمۡ جَسَدٗا لَّا يَأۡكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَمَا كَانُواْ خَٰلِدِينَ

A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kì í jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).[1] info

1. Gbígbé tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lọ sínú sánmọ̀ kò túmọ̀ sí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò níí kú. Rárá o, ó máa kú lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ nítorí pé, abara ni, kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu, Ọlọ́hun nìkan ni kò níí kú láéláé.

التفاسير: