Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael

Yuusuf

external-link copy
1 : 12

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ

’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 12

إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ

Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 12

نَحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ أَحۡسَنَ ٱلۡقَصَصِ بِمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ وَإِن كُنتَ مِن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ

Àwa ń sọ ìtàn tó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur’ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
4 : 12

إِذۡ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَٰٓأَبَتِ إِنِّي رَأَيۡتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوۡكَبٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ رَأَيۡتُهُمۡ لِي سَٰجِدِينَ

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.” info
التفاسير: