क़ुरआन के अर्थों का अनुवाद - योरुबा अनुवाद - अबू रहीमा मीकाईल

Ad-Duhaa

external-link copy
1 : 93

وَٱلضُّحَىٰ

Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 93

وَٱلَّيۡلِ إِذَا سَجَىٰ

Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 93

مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ

Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 93

وَلَلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لَّكَ مِنَ ٱلۡأُولَىٰ

Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 93

وَلَسَوۡفَ يُعۡطِيكَ رَبُّكَ فَتَرۡضَىٰٓ

Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 93

أَلَمۡ يَجِدۡكَ يَتِيمٗا فَـَٔاوَىٰ

Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 93

وَوَجَدَكَ ضَآلّٗا فَهَدَىٰ

Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.

التفاسير:

external-link copy
8 : 93

وَوَجَدَكَ عَآئِلٗا فَأَغۡنَىٰ

Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 93

فَأَمَّا ٱلۡيَتِيمَ فَلَا تَقۡهَرۡ

Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí). info
التفاسير:

external-link copy
10 : 93

وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنۡهَرۡ

Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn). info
التفاسير:

external-link copy
11 : 93

وَأَمَّا بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثۡ

Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde. info
التفاسير: