क़ुरआन के अर्थों का अनुवाद - योरुबा अनुवाद - अबू रहीमा मीकाईल

पृष्ठ संख्या:close

external-link copy
105 : 7

حَقِيقٌ عَلَىٰٓ أَن لَّآ أَقُولَ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّۚ قَدۡ جِئۡتُكُم بِبَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ فَأَرۡسِلۡ مَعِيَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ

Ẹ̀tọ́ ni fún mi pé èmi kò gbọdọ̀ ṣàfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo. Mo sì kúkú ti mú ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá mi lọ.” info
التفاسير:

external-link copy
106 : 7

قَالَ إِن كُنتَ جِئۡتَ بِـَٔايَةٖ فَأۡتِ بِهَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

(Fir‘aon) wí pé: “Tí o bá jẹ́ o mú àmì kan wá, mú un jáde tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.” info
التفاسير:

external-link copy
107 : 7

فَأَلۡقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعۡبَانٞ مُّبِينٞ

Nígbà náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé. info
التفاسير:

external-link copy
108 : 7

وَنَزَعَ يَدَهُۥ فَإِذَا هِيَ بَيۡضَآءُ لِلنَّٰظِرِينَ

Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ, ó sì di funfun (gbòlà) fún àwọn olùwòran. info
التفاسير:

external-link copy
109 : 7

قَالَ ٱلۡمَلَأُ مِن قَوۡمِ فِرۡعَوۡنَ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٌ عَلِيمٞ

Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa. info
التفاسير:

external-link copy
110 : 7

يُرِيدُ أَن يُخۡرِجَكُم مِّنۡ أَرۡضِكُمۡۖ فَمَاذَا تَأۡمُرُونَ

Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni.” (Fir‘aon wí pé: ) “Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:34.

التفاسير:

external-link copy
111 : 7

قَالُوٓاْ أَرۡجِهۡ وَأَخَاهُ وَأَرۡسِلۡ فِي ٱلۡمَدَآئِنِ حَٰشِرِينَ

Wọ́n sì wí pé: “Fún òun àti arákùnrin rẹ̀ lọ́jọ́,[1] kí o sì rán àwọn akónijọ² sí àwọn ìlú, info

1. Ọjọ́ ìpàdé náà ni ó jẹyọ nínú sūrah Tọ̄hā; 20:59. 2. Àwọn ni àwọn ọlọ́pàá Fir‘aon.

التفاسير:

external-link copy
112 : 7

يَأۡتُوكَ بِكُلِّ سَٰحِرٍ عَلِيمٖ

(pé) kí wọ́n mú gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ.” info
التفاسير:

external-link copy
113 : 7

وَجَآءَ ٱلسَّحَرَةُ فِرۡعَوۡنَ قَالُوٓاْ إِنَّ لَنَا لَأَجۡرًا إِن كُنَّا نَحۡنُ ٱلۡغَٰلِبِينَ

Àwọn òpìdán sì dé wá bá Fir‘aon. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú ẹ̀bùn gbọ́dọ̀ wà fún wa tí àwa bá jẹ́ olùborí.” info
التفاسير:

external-link copy
114 : 7

قَالَ نَعَمۡ وَإِنَّكُمۡ لَمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ

Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú ẹ̀yin gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).” info
التفاسير:

external-link copy
115 : 7

قَالُواْ يَٰمُوسَىٰٓ إِمَّآ أَن تُلۡقِيَ وَإِمَّآ أَن نَّكُونَ نَحۡنُ ٱلۡمُلۡقِينَ

(Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, o máa (kọ́kọ́) ju ọ̀pá sílẹ̀ ni, tàbí àwa ni a máa (kọ́kọ́) jù ú sílẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
116 : 7

قَالَ أَلۡقُواْۖ فَلَمَّآ أَلۡقَوۡاْ سَحَرُوٓاْ أَعۡيُنَ ٱلنَّاسِ وَٱسۡتَرۡهَبُوهُمۡ وَجَآءُو بِسِحۡرٍ عَظِيمٖ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, wọ́n lo àlùpàyídà lójú àwọn ènìyàn. Wọ́n sì ṣẹ̀rùbà wọ́n. Àní sẹ́ wọ́n pidán ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
117 : 7

۞ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَلۡقِ عَصَاكَۖ فَإِذَا هِيَ تَلۡقَفُ مَا يَأۡفِكُونَ

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” Nígbà náà, ó sì ń gbé ohun tí wọ́n ti pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló. info
التفاسير:

external-link copy
118 : 7

فَوَقَعَ ٱلۡحَقُّ وَبَطَلَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Nítorí náà, òdodo hàn (ó sì fìdí múlẹ̀). Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì bàjẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
119 : 7

فَغُلِبُواْ هُنَالِكَ وَٱنقَلَبُواْ صَٰغِرِينَ

Nítorí náà, A borí wọn níbẹ̀ yẹn. Wọ́n sì darí wálé ní ẹni yẹpẹrẹ. info
التفاسير:

external-link copy
120 : 7

وَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سَٰجِدِينَ

Iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). info
التفاسير: