क़ुरआन के अर्थों का अनुवाद - योरुबा अनुवाद - अबू रहीमा मीकाईल

पृष्ठ संख्या:close

external-link copy
39 : 17

ذَٰلِكَ مِمَّآ أَوۡحَىٰٓ إِلَيۡكَ رَبُّكَ مِنَ ٱلۡحِكۡمَةِۗ وَلَا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتُلۡقَىٰ فِي جَهَنَّمَ مَلُومٗا مَّدۡحُورًا

Ìyẹn wà nínú ohun tí Olúwa rẹ fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n (al-Ƙur’ān). Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu kí wọ́n má baà jù ọ́ sínú iná Jahanamọ ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
40 : 17

أَفَأَصۡفَىٰكُمۡ رَبُّكُم بِٱلۡبَنِينَ وَٱتَّخَذَ مِنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنَٰثًاۚ إِنَّكُمۡ لَتَقُولُونَ قَوۡلًا عَظِيمٗا

Ṣé Olúwa yín fi àwọn ọmọkùnrin ṣà yín lẹ́ṣà, Òun wá mú àwọn ọmọbìnrin nínú àwọn mọlāika (ní tiRẹ̀)? Dájúdájú ẹ mà ń sọ ọ̀rọ̀ ńlá (tó burú). info
التفاسير:

external-link copy
41 : 17

وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِيَذَّكَّرُواْ وَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا نُفُورٗا

Dájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí). info
التفاسير:

external-link copy
42 : 17

قُل لَّوۡ كَانَ مَعَهُۥٓ ءَالِهَةٞ كَمَا يَقُولُونَ إِذٗا لَّٱبۡتَغَوۡاْ إِلَىٰ ذِي ٱلۡعَرۡشِ سَبِيلٗا

Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.”[1] info

1. Ìyẹn ni pé, àwọn òrìṣà gan-an ń wá oore sọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.

التفاسير:

external-link copy
43 : 17

سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يَقُولُونَ عُلُوّٗا كَبِيرٗا

Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga ní gíga tó tóbi tayọ ohun tí wọ́n ń wí (ní àìda nípa Rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
44 : 17

تُسَبِّحُ لَهُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ ٱلسَّبۡعُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهِنَّۚ وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا يُسَبِّحُ بِحَمۡدِهِۦ وَلَٰكِن لَّا تَفۡقَهُونَ تَسۡبِيحَهُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورٗا

Àwọn sánmọ̀ méjèèje, ilẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wà nínú wọn ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. Kò sì sí kiní kan àfi kí ó máa ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.[1] Ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbọ́ àgbọ́yé àfọ̀mọ́ wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn. info

1. Ìyẹn ni pé, kò sí kiní kan tí kì í ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù.

التفاسير:

external-link copy
45 : 17

وَإِذَا قَرَأۡتَ ٱلۡقُرۡءَانَ جَعَلۡنَا بَيۡنَكَ وَبَيۡنَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ حِجَابٗا مَّسۡتُورٗا

Nígbà tí o bá ń ké al-Ƙur’ān, A máa fi gàgá ààbò sáààrin ìwọ àti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. info
التفاسير:

external-link copy
46 : 17

وَجَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۚ وَإِذَا ذَكَرۡتَ رَبَّكَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِ وَحۡدَهُۥ وَلَّوۡاْ عَلَىٰٓ أَدۡبَٰرِهِمۡ نُفُورٗا

A fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur’ān, wọ́n máa pẹ̀yìndà tí wọn yóò máa sá lọ. info
التفاسير:

external-link copy
47 : 17

نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَسۡتَمِعُونَ بِهِۦٓ إِذۡ يَسۡتَمِعُونَ إِلَيۡكَ وَإِذۡ هُمۡ نَجۡوَىٰٓ إِذۡ يَقُولُ ٱلظَّٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلٗا مَّسۡحُورًا

Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń gbọ́ nígbà tí wọ́n bá ń tẹ́tí sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, nígbà tí àwọn alábòsí bá ń wí pé: “Ẹ kò tẹ̀lé ẹnì kan bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.” info
التفاسير:

external-link copy
48 : 17

ٱنظُرۡ كَيۡفَ ضَرَبُواْ لَكَ ٱلۡأَمۡثَالَ فَضَلُّواْ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ سَبِيلٗا

Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà. info
التفاسير:

external-link copy
49 : 17

وَقَالُوٓاْ أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمٗا وَرُفَٰتًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ خَلۡقٗا جَدِيدٗا

Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a ti jẹrà, ṣé Wọ́n máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?” info
التفاسير: