1. “Faƙīr” ni aláìní, tálíkà, olòṣì. Ìyẹn ni ẹni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ́ tí kò rí iṣẹ́ kan kan ṣe, yálà lábẹ́ ènìyàn tàbí iṣẹ́ àdáni. Kò sì ní ọ̀nà kan kan tí ó lè gbà rí owó. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara tirẹ̀. “Miskīn” ni mẹ̀kúnnù. Ìyẹn ni ẹni tí ó ń rí iṣẹ́ kan ṣe, àmọ́ tí owó tó ń rí lórí iṣẹ́ náà kò ká àpapọ̀ bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀, owó ilé gbígbé rẹ̀ àti gbígbọ́ bùkátà lórí ará ilé rẹ̀. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi yanjú bùkátà ọrùn rẹ̀.