કુરઆન મજીદના શબ્દોનું ભાષાંતર - યોરૂબા ભાષામાં અનુવાદ - અબૂ રહીમા મિકાઈલ

Az-Zumar

external-link copy
1 : 39

تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ

Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀[1] láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.

التفاسير:

external-link copy
2 : 39

إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ فَٱعۡبُدِ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ

Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] info

1. Fífi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Allāhu ni sísin Allāhu, jíjọ́sìn fún Allāhu láti fi wá ojú rere Rẹ̀ nìkan ṣoṣo, tí kò sì níí fi ọ̀nà kan kan ròpọ̀ mọ́ ẹbọ ṣíṣe (ṣirk), ṣekárími (riyā’) àti ìṣọ̀bẹṣèlu (nifāƙ).

التفاسير:

external-link copy
3 : 39

أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلۡخَالِصُۚ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ مَا نَعۡبُدُهُمۡ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلۡفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ فِي مَا هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ كَٰذِبٞ كَفَّارٞ

Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́.[1] Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): “A kò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé, nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni.” Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́. info

1. Ẹ̀sìn mímọ́ ni ẹ̀sìn ’Islām tí wọ́n fi wá ojú rere Rẹ̀ nìkan ṣoṣo, tí kò sì níí fi ọ̀nà kan kan ròpọ̀ mọ́ ẹbọ ṣíṣe (ṣirk), ṣekárími (riyā’) àti ìṣọ̀bẹṣèlu (nifāƙ).

التفاسير:

external-link copy
4 : 39

لَّوۡ أَرَادَ ٱللَّهُ أَن يَتَّخِذَ وَلَدٗا لَّٱصۡطَفَىٰ مِمَّا يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ

Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 39

خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۖ يُكَوِّرُ ٱلَّيۡلَ عَلَى ٱلنَّهَارِ وَيُكَوِّرُ ٱلنَّهَارَ عَلَى ٱلَّيۡلِۖ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمًّىۗ أَلَا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّٰرُ

Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn. info
التفاسير: