Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

Al-Anfaal

external-link copy
1 : 8

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡأَنفَالِۖ قُلِ ٱلۡأَنفَالُ لِلَّهِ وَٱلرَّسُولِۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَصۡلِحُواْ ذَاتَ بَيۡنِكُمۡۖ وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير: