Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

external-link copy
144 : 7

قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ إِنِّي ٱصۡطَفَيۡتُكَ عَلَى ٱلنَّاسِ بِرِسَٰلَٰتِي وَبِكَلَٰمِي فَخُذۡ مَآ ءَاتَيۡتُكَ وَكُن مِّنَ ٱلشَّٰكِرِينَ

(Allāhu) sọ pé: “Mūsā, dájúdájú Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Mi àti ọ̀rọ̀ Mi.[1] Nítorí náà, gbá ohun tí Mo fún ọ mú. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́.” info

1. "Iṣẹ́ Mi" ìyẹn ni iṣẹ́ tí Allāhu fi rán Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí ìjọ rẹ̀. "Ọ̀rọ̀ Mi" ìyẹn ni ìbánisọ̀rọ̀ tó wáyé láààrin Allāhu àti Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́yìn gàgá tààrà láì lọ́wọ́ mọlāika nínú.

التفاسير: