Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

external-link copy
140 : 4

وَقَدۡ نَزَّلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ أَنۡ إِذَا سَمِعۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ يُكۡفَرُ بِهَا وَيُسۡتَهۡزَأُ بِهَا فَلَا تَقۡعُدُواْ مَعَهُمۡ حَتَّىٰ يَخُوضُواْ فِي حَدِيثٍ غَيۡرِهِۦٓ إِنَّكُمۡ إِذٗا مِّثۡلُهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ جَامِعُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡكَٰفِرِينَ فِي جَهَنَّمَ جَمِيعًا

(Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú bí irú wọn ni ẹ̀yin náà. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ. info
التفاسير: