Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

An-Nisaa'

external-link copy
1 : 4

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَخَلَقَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَبَثَّ مِنۡهُمَا رِجَالٗا كَثِيرٗا وَنِسَآءٗۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِي تَسَآءَلُونَ بِهِۦ وَٱلۡأَرۡحَامَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَيۡكُمۡ رَقِيبٗا

Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín. info
التفاسير: