Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

Tonngoode hello ngoo:close

external-link copy
12 : 31

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا لُقۡمَٰنَ ٱلۡحِكۡمَةَ أَنِ ٱشۡكُرۡ لِلَّهِۚ وَمَن يَشۡكُرۡ فَإِنَّمَا يَشۡكُرُ لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ حَمِيدٞ

Dájúdájú A ti fún Luƙmọ̄n ní ọgbọ́n, pé: “Dúpẹ́ fún Allāhu.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́, ó ń dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí). info
التفاسير:

external-link copy
13 : 31

وَإِذۡ قَالَ لُقۡمَٰنُ لِٱبۡنِهِۦ وَهُوَ يَعِظُهُۥ يَٰبُنَيَّ لَا تُشۡرِكۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّ ٱلشِّرۡكَ لَظُلۡمٌ عَظِيمٞ

(Rántí) nígbà tí Luƙmọ̄n sọ fún ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe wáàsí fún un, pé: “Ọmọ mi, má ṣe ṣẹbọ sí Allāhu. Dájúdájú ẹbọ ṣíṣe ni àbòsí ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 31

وَوَصَّيۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ بِوَٰلِدَيۡهِ حَمَلَتۡهُ أُمُّهُۥ وَهۡنًا عَلَىٰ وَهۡنٖ وَفِصَٰلُهُۥ فِي عَامَيۡنِ أَنِ ٱشۡكُرۡ لِي وَلِوَٰلِدَيۡكَ إِلَيَّ ٱلۡمَصِيرُ

Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì - (A sọ) pé: “Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì.” Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 31

وَإِن جَٰهَدَاكَ عَلَىٰٓ أَن تُشۡرِكَ بِي مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٞ فَلَا تُطِعۡهُمَاۖ وَصَاحِبۡهُمَا فِي ٱلدُّنۡيَا مَعۡرُوفٗاۖ وَٱتَّبِعۡ سَبِيلَ مَنۡ أَنَابَ إِلَيَّۚ ثُمَّ إِلَيَّ مَرۡجِعُكُمۡ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.[1] Fi dáadáa bá àwọn méjèèjì lòpọ̀ ní ilé ayé.² Kí o sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Mi (ní ti ìronúpìwàdà). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-‘Ankabūt; 29:8. 2. N̄ǹkan mẹ́ta ni dáadáa. Ìkíní: ohunkóhun tí āyah al-Ƙur’ān bá pè ní dáadáa, n̄ǹkan dáadáa ni. Ìkejì: ohunkóhun tí sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá pè ní dáadáa, n̄ǹkan dáadáa ni. Ìkẹta: ohunkóhun tí àṣà àti ìṣe ẹ̀yà ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan bá pè ní dáadáa, n̄ǹkan dáadáa ni ní òdíwọ̀n ìgbà tí āyah kan tàbí hadīth kan kò bá ti lòdì sí irúfẹ́ n̄ǹkan náà.

التفاسير:

external-link copy
16 : 31

يَٰبُنَيَّ إِنَّهَآ إِن تَكُ مِثۡقَالَ حَبَّةٖ مِّنۡ خَرۡدَلٖ فَتَكُن فِي صَخۡرَةٍ أَوۡ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ أَوۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَأۡتِ بِهَا ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٞ

Ọmọ mi, dájúdájú tí ó bá jẹ́ pé òdiwọ̀n èso kardal kan[1] ló wà nínú àpáta, tàbí nínú àwọn sánmọ̀, tàbí nínú ilẹ̀, Allāhu yóò mú un wá. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán. info

1. Ìyẹn dúró fún òdíwọ̀n tó kéré gan-an bíi ọmọ-iná igún.

التفاسير:

external-link copy
17 : 31

يَٰبُنَيَّ أَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ وَأۡمُرۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَٱنۡهَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَآ أَصَابَكَۖ إِنَّ ذَٰلِكَ مِنۡ عَزۡمِ ٱلۡأُمُورِ

Ọmọ mi, kírun, p’àṣẹ rere, kọ aburú, kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọ. Dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ tó pọn dandan. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 31

وَلَا تُصَعِّرۡ خَدَّكَ لِلنَّاسِ وَلَا تَمۡشِ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَحًاۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخۡتَالٖ فَخُورٖ

Má ṣe kọ párìkẹ́ rẹ sí ènìyàn. Má sì ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú fáàrí. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn gbogbo onígbèéraga, onífáàrí. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 31

وَٱقۡصِدۡ فِي مَشۡيِكَ وَٱغۡضُضۡ مِن صَوۡتِكَۚ إِنَّ أَنكَرَ ٱلۡأَصۡوَٰتِ لَصَوۡتُ ٱلۡحَمِيرِ

Jẹ́ kí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, kí o sì rẹ ohùn rẹ nílẹ̀. Dájúdájú ohùn tó burú jùlọ mà ni ohùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” info
التفاسير: