Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

external-link copy
4 : 17

وَقَضَيۡنَآ إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ لَتُفۡسِدُنَّ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَّتَيۡنِ وَلَتَعۡلُنَّ عُلُوّٗا كَبِيرٗا

A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì.[1] Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga tó tóbi.” info

1. Ìbàjẹ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ìsọ ti ìkìlọ̀, òhun ni pípa tí wọ́n máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Zakariyyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti pípa tí wọ́n tún máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a -.

التفاسير: