Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

Al-Is'raa'

external-link copy
1 : 17

سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِيٓ أَسۡرَىٰ بِعَبۡدِهِۦ لَيۡلٗا مِّنَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ إِلَى ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡأَقۡصَا ٱلَّذِي بَٰرَكۡنَا حَوۡلَهُۥ لِنُرِيَهُۥ مِنۡ ءَايَٰتِنَآۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ

Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.[1] info

1. Ìrìn-àjò òru tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - mú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rìn yìí, kì í ṣe nípasẹ̀ àlá lílá, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí àti ara.

التفاسير: