ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه‌ى یوروبایی - ابو رحیمه میکائیل

An-Naba'

external-link copy
1 : 78

عَمَّ يَتَسَآءَلُونَ

Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná? info
التفاسير:

external-link copy
2 : 78

عَنِ ٱلنَّبَإِ ٱلۡعَظِيمِ

Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni, info
التفاسير:

external-link copy
3 : 78

ٱلَّذِي هُمۡ فِيهِ مُخۡتَلِفُونَ

èyí tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 78

كَلَّا سَيَعۡلَمُونَ

Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 78

ثُمَّ كَلَّا سَيَعۡلَمُونَ

Lẹ́yìn náà, rárá sẹ́, wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 78

أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ مِهَٰدٗا

Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí, info
التفاسير:

external-link copy
7 : 78

وَٱلۡجِبَالَ أَوۡتَادٗا

àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)? info
التفاسير:

external-link copy
8 : 78

وَخَلَقۡنَٰكُمۡ أَزۡوَٰجٗا

A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo). info
التفاسير:

external-link copy
9 : 78

وَجَعَلۡنَا نَوۡمَكُمۡ سُبَاتٗا

A ṣe oorun yín ní ìsinmi. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 78

وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ لِبَاسٗا

A tún ṣe alẹ́ ní ìbora. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 78

وَجَعَلۡنَا ٱلنَّهَارَ مَعَاشٗا

A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 78

وَبَنَيۡنَا فَوۡقَكُمۡ سَبۡعٗا شِدَادٗا

A tún mọ sánmọ̀ méje tó lágbára sókè yín. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 78

وَجَعَلۡنَا سِرَاجٗا وَهَّاجٗا

A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn gbòlà. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 78

وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلۡمُعۡصِرَٰتِ مَآءٗ ثَجَّاجٗا

Àti pé A sọ omi tó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò info
التفاسير:

external-link copy
15 : 78

لِّنُخۡرِجَ بِهِۦ حَبّٗا وَنَبَاتٗا

nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde info
التفاسير:

external-link copy
16 : 78

وَجَنَّٰتٍ أَلۡفَافًا

pẹ̀lú àwọn ọgbà tó kún digbí fún n̄ǹkan oko. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 78

إِنَّ يَوۡمَ ٱلۡفَصۡلِ كَانَ مِيقَٰتٗا

Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 78

يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِ فَتَأۡتُونَ أَفۡوَاجٗا

(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 78

وَفُتِحَتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتۡ أَبۡوَٰبٗا

Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 78

وَسُيِّرَتِ ٱلۡجِبَالُ فَكَانَتۡ سَرَابًا

Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 78

إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتۡ مِرۡصَادٗا

Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 78

لِّلطَّٰغِينَ مَـَٔابٗا

(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ. info
التفاسير:

external-link copy
23 : 78

لَّٰبِثِينَ فِيهَآ أَحۡقَابٗا

Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 78

لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرۡدٗا وَلَا شَرَابًا

Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀, info
التفاسير:

external-link copy
25 : 78

إِلَّا حَمِيمٗا وَغَسَّاقٗا

àyàfi omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 78

جَزَآءٗ وِفَاقًا

(Ó jẹ́) ẹ̀san tó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn). info
التفاسير:

external-link copy
27 : 78

إِنَّهُمۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ حِسَابٗا

Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
28 : 78

وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا كِذَّابٗا

Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́ gan-an. info
التفاسير:

external-link copy
29 : 78

وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ كِتَٰبٗا

Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan. info
التفاسير:

external-link copy
30 : 78

فَذُوقُواْ فَلَن نَّزِيدَكُمۡ إِلَّا عَذَابًا

Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fún yín bí kò ṣe ìyà. info
التفاسير: