আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ - ইউৰুবা অনুবাদ - আবু ৰাহীমাহ মিকাঈল

Al-Mutoffifiin

external-link copy
1 : 83

وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ

Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù, info
التفاسير:

external-link copy
2 : 83

ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ

àwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,[1] wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún, info

1. “Àwọn ènìyàn” ní àyè yìí dúró fún bíi “ àwọn olóko”.

التفاسير:

external-link copy
3 : 83

وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ

nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 83

أَلَا يَظُنُّ أُوْلَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ

Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde info
التفاسير:

external-link copy
5 : 83

لِيَوۡمٍ عَظِيمٖ

ní Ọjọ́ ńlá kan? info
التفاسير:

external-link copy
6 : 83

يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 83

كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٖ

Ní ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 83

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينٞ

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn! info
التفاسير:

external-link copy
9 : 83

كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ

Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn). info
التفاسير:

external-link copy
10 : 83

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́, info
التفاسير:

external-link copy
11 : 83

ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ

àwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 83

وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ

Kò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 83

إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ

Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).” info
التفاسير:

external-link copy
14 : 83

كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ

Rárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 83

كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّمَحۡجُوبُونَ

Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 83

ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 83

ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.” info
التفاسير:

external-link copy
18 : 83

كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ

Ní ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 83

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn! info
التفاسير:

external-link copy
20 : 83

كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ

Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn). info
التفاسير:

external-link copy
21 : 83

يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ

Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 83

إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ

Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn. info
التفاسير:

external-link copy
23 : 83

عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ

Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 83

تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ

Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 83

يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقٖ مَّخۡتُومٍ

Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 83

خِتَٰمُهُۥ مِسۡكٞۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ

Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 83

وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ

Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà). info
التفاسير:

external-link copy
28 : 83

عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ

(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu. info
التفاسير:

external-link copy
29 : 83

إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ

Dájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín. info
التفاسير:

external-link copy
30 : 83

وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ

Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
31 : 83

وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ

Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí. info
التفاسير:

external-link copy
32 : 83

وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.” info
التفاسير:

external-link copy
33 : 83

وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ

Àwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
34 : 83

فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ

Nítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín. info
التفاسير:

external-link copy
35 : 83

عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ

Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn. info
التفاسير:

external-link copy
36 : 83

هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ

Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)? info
التفاسير: