আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ - ইউৰুবা অনুবাদ - আবু ৰাহীমাহ মিকাঈল

Abasa

external-link copy
1 : 80

عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ

Ó fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà[1] info

1. Ìyẹn ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà.

التفاسير:

external-link copy
2 : 80

أَن جَآءَهُ ٱلۡأَعۡمَىٰ

nítorí pé afọ́jú wá bá a. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 80

وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ

Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́) info
التفاسير:

external-link copy
4 : 80

أَوۡ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكۡرَىٰٓ

tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní? info
التفاسير:

external-link copy
5 : 80

أَمَّا مَنِ ٱسۡتَغۡنَىٰ

Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀, info
التفاسير:

external-link copy
6 : 80

فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ

òun ni ìwọ tẹ́tí sí. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 80

وَمَا عَلَيۡكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ

Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́). info
التفاسير:

external-link copy
8 : 80

وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسۡعَىٰ

Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú), info
التفاسير:

external-link copy
9 : 80

وَهُوَ يَخۡشَىٰ

tí ó sì ń páyà (Allāhu), info
التفاسير:

external-link copy
10 : 80

فَأَنتَ عَنۡهُ تَلَهَّىٰ

ìwọ kò sì kọbi ara sí i. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 80

كَلَّآ إِنَّهَا تَذۡكِرَةٞ

Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 80

فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 80

فِي صُحُفٖ مُّكَرَّمَةٖ

(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé, info
التفاسير:

external-link copy
14 : 80

مَّرۡفُوعَةٖ مُّطَهَّرَةِۭ

A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́ info
التفاسير:

external-link copy
15 : 80

بِأَيۡدِي سَفَرَةٖ

ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika), info
التفاسير:

external-link copy
16 : 80

كِرَامِۭ بَرَرَةٖ

àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 80

قُتِلَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَآ أَكۡفَرَهُۥ

Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ! info
التفاسير:

external-link copy
18 : 80

مِنۡ أَيِّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥ

Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀? info
التفاسير:

external-link copy
19 : 80

مِن نُّطۡفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ

Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 80

ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ

Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 80

ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقۡبَرَهُۥ

Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 80

ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ

Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde. info
التفاسير:

external-link copy
23 : 80

كَلَّا لَمَّا يَقۡضِ مَآ أَمَرَهُۥ

Rárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 80

فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ

Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 80

أَنَّا صَبَبۡنَا ٱلۡمَآءَ صَبّٗا

Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 80

ثُمَّ شَقَقۡنَا ٱلۡأَرۡضَ شَقّٗا

Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 80

فَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا حَبّٗا

A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀; info
التفاسير:

external-link copy
28 : 80

وَعِنَبٗا وَقَضۡبٗا

àti èso àjàrà àti kànnáfùrù, info
التفاسير:

external-link copy
29 : 80

وَزَيۡتُونٗا وَنَخۡلٗا

àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù, info
التفاسير:

external-link copy
30 : 80

وَحَدَآئِقَ غُلۡبٗا

àti àwọn ọgbà tó kún fún igi, info
التفاسير:

external-link copy
31 : 80

وَفَٰكِهَةٗ وَأَبّٗا

àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde). info
التفاسير:

external-link copy
32 : 80

مَّتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ

(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. info
التفاسير:

external-link copy
33 : 80

فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ

Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀, info
التفاسير:

external-link copy
34 : 80

يَوۡمَ يَفِرُّ ٱلۡمَرۡءُ مِنۡ أَخِيهِ

ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀, info
التفاسير:

external-link copy
35 : 80

وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ

àti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀, info
التفاسير:

external-link copy
36 : 80

وَصَٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ

àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
37 : 80

لِكُلِّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ يَوۡمَئِذٖ شَأۡنٞ يُغۡنِيهِ

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán. info
التفاسير:

external-link copy
38 : 80

وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٖ مُّسۡفِرَةٞ

Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
39 : 80

ضَاحِكَةٞ مُّسۡتَبۡشِرَةٞ

Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú. info
التفاسير:

external-link copy
40 : 80

وَوُجُوهٞ يَوۡمَئِذٍ عَلَيۡهَا غَبَرَةٞ

Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
41 : 80

تَرۡهَقُهَا قَتَرَةٌ

Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
42 : 80

أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَفَرَةُ ٱلۡفَجَرَةُ

Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير: