আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ - ইউৰুবা অনুবাদ - আবু ৰাহীমাহ মিকাঈল

Al-Mahaarij

external-link copy
1 : 70

سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ

Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀ info
التفاسير:

external-link copy
2 : 70

لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ

sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́ info
التفاسير:

external-link copy
3 : 70

مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ

lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 70

تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ

Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).[1] info

1. Ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ọdún (50,000). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:47.

التفاسير:

external-link copy
5 : 70

فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا

Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 70

إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا

Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 70

وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا

A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 70

يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ

(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 70

وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ

àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun, info
التفاسير:

external-link copy
10 : 70

وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا

ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
11 : 70

يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ

Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 70

وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ

Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀, info
التفاسير:

external-link copy
13 : 70

وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ

àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé, info
التفاسير:

external-link copy
14 : 70

وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ يُنجِيهِ

àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná). info
التفاسير:

external-link copy
15 : 70

كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ

Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò). info
التفاسير:

external-link copy
16 : 70

نَزَّاعَةٗ لِّلشَّوَىٰ

Ó máa bó awọ orí tòró. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 70

تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ

(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i, info
التفاسير:

external-link copy
18 : 70

وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ

ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn). info
التفاسير:

external-link copy
19 : 70

۞ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا

Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 70

إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعٗا

Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 70

وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا

Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 70

إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ

Àyàfi àwọn olùkírun, info
التفاسير:

external-link copy
23 : 70

ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ

àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn; info
التفاسير:

external-link copy
24 : 70

وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ مَّعۡلُومٞ

àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn info
التفاسير:

external-link copy
25 : 70

لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ

sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún; info
التفاسير:

external-link copy
26 : 70

وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ

àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo; info
التفاسير:

external-link copy
27 : 70

وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ

àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn, info
التفاسير:

external-link copy
28 : 70

إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٖ

dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí; info
التفاسير:

external-link copy
29 : 70

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ

àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn, info
التفاسير:

external-link copy
30 : 70

إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ

àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú, info
التفاسير:

external-link copy
31 : 70

فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ

nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà; info
التفاسير:

external-link copy
32 : 70

وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ

àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn; info
التفاسير:

external-link copy
33 : 70

وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ

àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn; info
التفاسير:

external-link copy
34 : 70

وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ

àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn. info
التفاسير:

external-link copy
35 : 70

أُوْلَٰٓئِكَ فِي جَنَّٰتٖ مُّكۡرَمُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. info
التفاسير:

external-link copy
36 : 70

فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ

Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ, info
التفاسير:

external-link copy
37 : 70

عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ

tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)? info
التفاسير:

external-link copy
38 : 70

أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٖ

Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni? info
التفاسير:

external-link copy
39 : 70

كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ

Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
40 : 70

فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ

Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn[1] búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára info

1. Ìyẹn ni pé, Èmi, Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn ń fi ara Mi búra.

التفاسير:

external-link copy
41 : 70

عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ

láti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.[1] info

1. Ẹ tún wo sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:60-61 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:3-4.

التفاسير:

external-link copy
42 : 70

فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ

Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
43 : 70

يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ

Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan. info
التفاسير:

external-link copy
44 : 70

خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ

Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. info
التفاسير: