1. Ìyẹn ni pé, Iná fúnra rẹ̀ yóò máa bínú sí àwọn èrò inú rẹ̀ tí ìbínú rẹ̀ yóò máa mú un ru sókè bíi ríru omi òkun, yóò sì máa jà bí ìjì atẹ́gùn bíi pé ó fẹ́ fà wọ́n ya jálajàla.
1. Ìyẹn ni pé, tí ẹ̀dá bá lérò pé, bí òun bá sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀, ó yẹ kí ẹ̀dá náà mọ̀ dájú pé, nínú ìròyìn Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni pé, Ẹlẹ́dàá nímọ̀ èrò-ọkàn àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ sọ ní ìkọ̀kọ̀. Ìtúmọ̀ kejí: “Ṣé Allāhu kò mọ ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?” Ìyẹn ni pé, ṣé Allāhu kò mọ àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tòhun tí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn, ọ̀rọ̀ gban̄gba wọn àti èrò-ọkàn wọn? Allāhu mọ gbogbo rẹ̀.
1. Ta ni Ẹni náà tí Ó wà ní òkè sánmọ̀ bí kò ṣe Allāhu - Ọba tó ga jùlọ -.
1. Sūrah al-Mulk àti sūrah as-Sajdah jẹ́ sūrah tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ń ké ní alaalẹ́ ní ojoojúmọ́. Ààbò ló jẹ́ níbi ìyá nínú sàréè, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú hadīth Nasā’iy àti òmíràn.