"1. È é ti ṣe tí Allāhu lẹ́yìn tí Ó sọ pé “Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ.” kò fi kún un pé, “àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ”? Ìdí ni pé, Allāhu ti fi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe òpin àwọn arímìísígbà “kātamu-nnabiyyīn”. Ẹ wo sūrah al-’Ahzāb; 33:40.
1. Ìyẹn ni pe, kí á ṣẹ́rí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyapa-ẹnu bá wáyé lórí wọn sínú al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀.