1. Gbólóhùn yìí ba àwọn Sọhābah nínú jẹ́ gidigidi, àmọ́ Allāhu dẹ̀ ẹ́ fún wọn nínú āyah tí ó parí sūrah yìí.
1. Kíyè sí i, ìgbàgbọ́ àwa ọmọlẹ́yìn Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - nínú àwọn Tírà àti àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá wọn - tí gbogbo wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn ’Islām kò túmọ̀ sí títẹ̀lé wọn nínú ìlànà ìjọ́sìn wọn àti ìdájọ́ ṣíṣe ní àsìkò yìí.