আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ - ইউৰুবা অনুবাদ - আবু ৰাহীমাহ মিকাঈল

Al-Humazah

external-link copy
1 : 104

وَيۡلٞ لِّكُلِّ هُمَزَةٖ لُّمَزَةٍ

Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni, info
التفاسير:

external-link copy
2 : 104

ٱلَّذِي جَمَعَ مَالٗا وَعَدَّدَهُۥ

ẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn). info
التفاسير:

external-link copy
3 : 104

يَحۡسَبُ أَنَّ مَالَهُۥٓ أَخۡلَدَهُۥ

Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé). info
التفاسير:

external-link copy
4 : 104

كَلَّاۖ لَيُنۢبَذَنَّ فِي ٱلۡحُطَمَةِ

Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 104

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحُطَمَةُ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh? info
التفاسير:

external-link copy
6 : 104

نَارُ ٱللَّهِ ٱلۡمُوقَدَةُ

(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere), info
التفاسير:

external-link copy
7 : 104

ٱلَّتِي تَطَّلِعُ عَلَى ٱلۡأَفۡـِٔدَةِ

èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 104

إِنَّهَا عَلَيۡهِم مُّؤۡصَدَةٞ

Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 104

فِي عَمَدٖ مُّمَدَّدَةِۭ

(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná). info
التفاسير: