1. Àsìkò tí àwọn mọlāika fẹ́ pa ìjọ Ànábì Lūt - kí ọlà Allāhu máa bá a - rẹ́ ni àsìkò tí ìró ìdùnnú àsọtẹ́lẹ̀ bíbí Ànábì ’Ishāƙ - kí ọlà Allāhu máa bá a - bọ́ sí. Èyí túmọ̀ sí pé, lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti fẹ́ fi àkọ́bí rẹ̀ Ànábì ’Ismọ̄‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - jọ́sìn fún Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - ni àsọtẹ́lẹ̀ bíbí Ànábì ’Ishāƙ - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣẹlẹ̀.